Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 14:24-35 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Nítorí kò sí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́kọ́ pè tí yóo tọ́ wò ninu àsè mi!’ ”

25. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan péjọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá yíjú pada sí wọn, ó ní,

26. “Bí ẹnìkan bá fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá kórìíra baba rẹ̀ ati ìyá rẹ̀, ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati ẹ̀gbọ́n, ati àbúrò rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí ó fi mọ́ ẹ̀mí òun pàápàá, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

27. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

28. “Nítorí ta ni ninu yín tí yóo fẹ́ kọ́ ilé ńlá kan, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye tí yóo ná òun, kí ó mọ̀ bí òun bá ní ohun tí òun yóo fi parí rẹ̀?

29. Kí ó má wá jẹ́ pé yóo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ tán, kò ní lè parí rẹ̀ mọ́. Gbogbo àwọn tí ó bá rí i yóo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́.

30. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọkunrin yìí bẹ̀rẹ̀ ilé, kò lè parí rẹ̀!’

31. “Tabi ọba wo ni yóo lọ ko ọba mìíràn lójú ogun tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó gba ìmọ̀ràn bí òun yóo bá lè ko ẹni tí ó ní ọ̀kẹ́ kan ọmọ-ogun lójú?

32. Bí kò bá ní lè kò ó lójú, kí ọ̀tá rẹ̀ tó dé ìtòsí, yóo tètè rán ikọ̀ sí i pé òun túúbá.

33. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni ninu yín tí kò bá kọ gbogbo ohun tí ó ní sílẹ̀, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

34. “Iyọ̀ dára. Ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni a ti ṣe lè mú kí ó tún dùn?

35. Kó wúlò fún oko tabi fún ààtàn mọ́ àfi kí á dà á sóde. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Ka pipe ipin Luku 14