Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 14:18-24 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ni gbogbo wọn patapata láìku ẹnìkan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ekinni sọ fún un pé, ‘Mo ra ilẹ̀ kan, mo sì níláti lọ wò ó. Mo tọrọ àforíjì, yọ̀ǹda mi.’

19. Ẹnìkejì ní, ‘Mo ra mààlúù fún ẹ̀rọ-ìroko. Mò ń lọ dán an wò, dákun, yọ̀ǹda mi.’

20. Ẹnìkẹta ní, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iyawo ni, nítorí náà n kò lè wá.’

21. “Iranṣẹ náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún oluwa rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Tètè lọ sí gbogbo títì ati ọ̀nà ẹ̀bùrú ìlú, kí o lọ kó àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú, ati àwọn arọ wá síhìn-ín.’

22. Nígbà tí iranṣẹ náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, ó ní, ‘Alàgbà, a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, sibẹ àyè tún kù.’

23. Oluwa iranṣẹ náà sọ fún un pé, ‘Lọ sí ọ̀nà oko, kí o bẹ àwọn ẹni tí o bá rí, kí wọ́n wọlé wá, kí inú ilé mi baà kún.

24. Nítorí kò sí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́kọ́ pè tí yóo tọ́ wò ninu àsè mi!’ ”

Ka pipe ipin Luku 14