Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 14:1-20 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, Jesu lọ jẹun ní ilé ọ̀kan ninu àwọn olóyè láàrin àwọn Farisi. Wọ́n bá ń ṣọ́ ọ.

2. Ọkunrin kan wà níwájú rẹ̀ níbẹ̀ tí gbogbo ara rẹ̀ wú bòmù-bòmù.

3. Jesu bi àwọn amòfin ati àwọn Farisi tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ṣé ó dára láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, tabi kò dára?”

4. Wọ́n bá dákẹ́. Jesu bá mú ọkunrin náà, ó wò ó sàn, ó bá ní kí ó máa lọ.

5. Ó wá bi wọ́n pé, “Ta ni ninu yín tí ọmọ rẹ̀, tabi mààlúù rẹ̀ yóo já sinu kànga ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á yọ lẹsẹkẹsẹ?”

6. Wọn kò sì lè dá a lóhùn.

7. Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní,

8. “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ sí ibi iyawo, má ṣe lọ jókòó ní ipò ọlá. Bóyá ẹni tí ó pè ọ́ tún pe ẹlòmíràn tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.

9. Ẹni tí ó pè ọ́ yóo wá tọ̀ ọ́ wá, yóo sọ fún ọ pé, ‘Fi ààyè fún ọkunrin yìí,’ Ìwọ yóo wá fi ìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ààyè lẹ́yìn.

10. Tí wọn bá pè ọ́, lọ jókòó lẹ́yìn, kí ẹni tí ó pè ọ́ lè wá sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi súnmọ́ iwájú.’ Nígbà náà ìwọ yóo ní iyì lójú gbogbo àwọn tí ó wà níbi àsè.

11. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”

12. Ó wá sọ fún ẹni tí ó pè é fún oúnjẹ pé, “Nígbà tí o bá se àsè, ìbáà jẹ́ lọ́sàn-án tabi lálẹ́, má ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tabi àwọn arakunrin rẹ tabi àwọn ẹbí rẹ tabi àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bí o bá pè wọ́n, àwọn náà yóo pè ọ́ wá jẹun níjọ́ mìíràn, wọn yóo sì san oore tí o ṣe wọ́n pada fún ọ.

13. Ṣugbọn bí o bá se àsè, pe àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú.

14. Èyí ni yóo fún ọ láyọ̀, nítorí wọn kò lè san án pada fún ọ. Ṣugbọn Ọlọrun yóo san án pada fún ọ nígbà tí àwọn olódodo bá jí dìde kúrò ninu òkú.”

15. Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn tí ó wà níbi àsè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún Jesu pé, “Ẹni tí ó bá jẹun ní ìjọba ọ̀run ṣe oríire!”

16. Jesu sọ fún un pé, “Ọkunrin kan se àsè ńlá kan; ó pe ọ̀pọ̀ eniyan sibẹ.

17. Nígbà tí àkókò ati jẹun tó, ó rán iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti pè láti sọ fún wọn pé, ‘Ó yá o! A ti ṣetán!’

18. Ni gbogbo wọn patapata láìku ẹnìkan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ekinni sọ fún un pé, ‘Mo ra ilẹ̀ kan, mo sì níláti lọ wò ó. Mo tọrọ àforíjì, yọ̀ǹda mi.’

19. Ẹnìkejì ní, ‘Mo ra mààlúù fún ẹ̀rọ-ìroko. Mò ń lọ dán an wò, dákun, yọ̀ǹda mi.’

20. Ẹnìkẹta ní, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iyawo ni, nítorí náà n kò lè wá.’

Ka pipe ipin Luku 14