Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 12:55-59 BIBELI MIMỌ (BM)

55. Bí atẹ́gùn bá fẹ́ wá láti gúsù, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ooru yóo mú,’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí.

56. Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ mọ àmì ilẹ̀ ati ti ojú sánmà, ṣugbọn ẹ kò mọ àmì àkókò yìí!

57. “Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà?

58. Bí o bá ń bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ lọ sí kóòtù, gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹlu rẹ̀ bí ẹ ti ń lọ lọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́. Onídàájọ́ yóo bá fi ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ni ọlọ́pàá yóo bá tì ọ́ mọ́lé.

59. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé, o kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí o óo fi san gbogbo gbèsè tí o jẹ, láìku kọbọ!”

Ka pipe ipin Luku 12