Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 11:32-48 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Àwọn eniyan Ninefe yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, wọn yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nígbà tí Jona waasu fún wọn. Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Jona lọ wà níhìn-ín.

33. “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ tan fìtílà, tí ó jẹ́ fi pamọ́, tabi kí ó fi igbá bò ó. Ńṣe ni yóo gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà kí àwọn tí ó bá ń wọlé lè ríran.

34. Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn.

35. Nítorí náà kí ẹ ṣọ́ra kí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu yín má baà jẹ́ òkùnkùn.

36. Bí gbogbo ara rẹ bá ní ìmọ́lẹ̀, tí kò sí ibìkan tí ó ṣókùnkùn, ńṣe ni yóo mọ́lẹ̀ bí ìgbà tí àtùpà bá tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”

37. Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Farisi kan pè é pé kí ó wá jẹun ninu ilé rẹ̀. Ó bá wọlé, ó jókòó.

38. Ẹnu ya Farisi náà nígbà tí ó rí i pé Jesu kò kọ́kọ́ wẹwọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun.

39. Oluwa wá sọ fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa fọ òde kọ́ọ̀bù ati àwo oúnjẹ, ṣugbọn inú yín kún fún ìwà ipá ati nǹkan burúkú!

40. Ẹ̀yin aṣiwèrè wọnyi! Mo ṣebí ẹni tí ó dá òde, òun náà ni ó dá inú.

41. Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín.

42. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà.

43. “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà.

44. Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”

45. Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!”

46. Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan.

47. Ẹ gbé! Nítorí ẹ̀ ń kọ́ ibojì àwọn wolii, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn baba yín ni wọ́n pa wọ́n.

48. Ṣíṣe tí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fi yín hàn bí ẹlẹ́rìí pé ẹ lóhùn sí ìwà àwọn baba yín: wọ́n pa àwọn wolii, ẹ̀yin wá ṣe ibojì sí ojú-oórì wọn.

Ka pipe ipin Luku 11