Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 1:68-76 BIBELI MIMỌ (BM)

68. Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹlinítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀,ó sì ti dá wọn nídè.

69. Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún waní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀;

70. gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́,láti ọjọ́ pípẹ́;

71. pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá waati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;

72. pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò,ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́

73. gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa,

74. pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà,

75. pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodoníwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

76. “Ìwọ, ọmọ mi,wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́,nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é,

Ka pipe ipin Luku 1