Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 1:63-75 BIBELI MIMỌ (BM)

63. Ó bá bèèrè fún nǹkan ìkọ̀wé, ó kọ ọ́ pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu ya gbogbo eniyan.

64. Lẹsẹkẹsẹ ohùn Sakaraya bá là, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀, ó ń yin Ọlọrun.

65. Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo àwọn aládùúgbò wọn. Ìròyìn tàn ká gbogbo agbègbè olókè Judia, wọ́n ń sọ ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀.

66. Gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ń da ọ̀rọ̀ náà rò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń sọ pé, “Irú ọmọ wo ni èyí yóo jẹ́?” Nítorí ọwọ́ Oluwa wà lára rẹ̀.

67. Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé,

68. Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹlinítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀,ó sì ti dá wọn nídè.

69. Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún waní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀;

70. gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́,láti ọjọ́ pípẹ́;

71. pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá waati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;

72. pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò,ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́

73. gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa,

74. pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà,

75. pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodoníwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

Ka pipe ipin Luku 1