54. Ó ran Israẹli ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́nígbà tí ó ranti àánú rẹ̀,
55. gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí ó ti ṣe fún àwọn baba wa:fún Abrahamu ati fún ìdílé rẹ̀ títí lae.”
56. Maria dúró lọ́dọ̀ Elisabẹti tó bíi oṣù mẹta, ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀.
57. Nígbà tí àkókò Elisabẹti tó tí yóo bí, ó bí ọmọkunrin kan.
58. Àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Oluwa ti ṣàánú pupọ fún un, wọ́n wá bá a yọ̀.
59. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti kọ́ ọmọ náà ní ilà-abẹ́. Wọ́n fẹ́ sọ ọ́ ní Sakaraya, bí orúkọ baba rẹ̀.
60. Ṣugbọn ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Rárá o! Johanu ni a óo máa pè é.”
61. Wọ́n sọ fún un pé, “Kò sí ẹnìkan ninu àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí ó ń jẹ́ orúkọ yìí.”
62. Wọ́n wá ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀ pé báwo ni ó fẹ́ kí á máa pe ọmọ náà.