Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 1:22-34 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Nígbà tí ó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti rí ìran ninu iyàrá Tẹmpili ni. Ó yadi, ọwọ́ ni ó fi ń ṣe àpèjúwe fún wọn.

23. Nígbà tí ó parí àkókò tí yóo fi ṣiṣẹ́ alufaa ninu Tẹmpili, ó pada lọ sí ilé rẹ̀.

24. Lẹ́yìn náà, Elisabẹti lóyún. Ó bá fi ara pamọ́ fún oṣù marun-un. Ó ní,

25. “Oluwa ni ó ṣe èyí fún mi. Ó ti fi ojú àánú wò mí, ó sì ti mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀gàn fún mi lójú eniyan kúrò.”

26. Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti.

27. Ọlọrun rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wundia kan tí ó jẹ́ iyawo àfẹ́sọ́nà ọkunrin kan tí ń jẹ́ Josẹfu, ti ìdílé Dafidi. Wundia náà ń jẹ́ Maria.

28. Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.”

29. Nígbà tí Maria gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ń rò lọ́kàn rẹ̀ pé, irú kíkí wo nìyí?

30. Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé.

31. O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀.

32. Eniyan ńlá ni yóo jẹ́. Ọmọ Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè é. Oluwa Ọlọrun yóo fún un ní ìtẹ́ Dafidi, baba rẹ̀.

33. Yóo jọba lórí ìdílé Jakọbu títí lae, ìjọba rẹ̀ kò ní lópin.”

34. Maria bá bi angẹli náà pé, “Báwo ni yóo ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí n kò tíì mọ ọkunrin?”

Ka pipe ipin Luku 1