Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 4:3-16 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Kò ṣe mí ní nǹkankan bí ẹ bá ń dá mi lẹ́jọ́ tabi bí ẹnikẹ́ni bá ń dá mi lẹ́jọ́. Èmi fúnra mi kì í tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.

4. Ọkàn mi mọ́, ṣugbọn n kò wí pé mo pé, Oluwa ni ẹni tí ó ń ṣe ìdájọ́ mi.

5. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

6. Ẹ̀yin ará, mo fi ara mi ati Apolo ṣe àpẹẹrẹ ohun tí à ń sọ nítorí yín, kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa, pé kí ẹ má ṣe tayọ ohun tí ó wà ní àkọsílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹnìkejì lọ.

7. Ta ni ó gbe yín ga ju ẹlòmíràn lọ? Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà? Kí wá ni ìdí ìgbéraga yín bí ẹni pé ẹ̀yin ni ẹ dá a ní?

8. Ṣé gbogbo nǹkan ti tẹ yín lọ́rùn! Ẹ ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ gbàgbé wa sẹ́yìn, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí jọba! Kì bá wù mí kí ẹ jọba nítòótọ́ kí àwa náà lè ba yín jọba!

9. Nítorí mo rò pé Ọlọrun ti fi àwa òjíṣẹ́ hàn ní ìkẹyìn bí àwọn tí a dá lẹ́bi ikú, nítorí a ti di ẹni tí gbogbo ayé fi ń ṣe ìran wò: ati àwọn angẹli, ati àwọn eniyan.

10. Àwa di òmùgọ̀ nítorí ti Kristi, ẹ̀yin wá jẹ́ ọlọ́gbọ́n ninu Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́lá, àwa jẹ́ aláìlọ́lá!

11. Títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ebi ń pa wá, òùngbẹ ń gbẹ wá, aṣọ sì di àkísà mọ́ wa lára. Wọ́n ń lù wá, a kò sì ní ibùgbé kan tààrà.

12. Àárẹ̀ mú wa bí a ti ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. Àwọn eniyan ń bú wa, ṣugbọn àwa ń súre fún wọn. Wọ́n ń ṣe inúnibíni wa, ṣugbọn à ń fara dà á.

13. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, ṣugbọn àwa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí. A di ohun ẹ̀sín fún gbogbo ayé. A di pàǹtí fún gbogbo eniyan títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.

14. Kì í ṣe pé mo fẹ́ dójú tì yín ni mo fi ń kọ nǹkan wọnyi si yín, mò ń kìlọ̀ fun yín gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ mi ni.

15. Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.

16. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìwà jọ mí.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 4