Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 4:10-21 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Àwa di òmùgọ̀ nítorí ti Kristi, ẹ̀yin wá jẹ́ ọlọ́gbọ́n ninu Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́lá, àwa jẹ́ aláìlọ́lá!

11. Títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ebi ń pa wá, òùngbẹ ń gbẹ wá, aṣọ sì di àkísà mọ́ wa lára. Wọ́n ń lù wá, a kò sì ní ibùgbé kan tààrà.

12. Àárẹ̀ mú wa bí a ti ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. Àwọn eniyan ń bú wa, ṣugbọn àwa ń súre fún wọn. Wọ́n ń ṣe inúnibíni wa, ṣugbọn à ń fara dà á.

13. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, ṣugbọn àwa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí. A di ohun ẹ̀sín fún gbogbo ayé. A di pàǹtí fún gbogbo eniyan títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.

14. Kì í ṣe pé mo fẹ́ dójú tì yín ni mo fi ń kọ nǹkan wọnyi si yín, mò ń kìlọ̀ fun yín gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ mi ni.

15. Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.

16. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìwà jọ mí.

17. Ìdí tí mo ṣe rán Timoti si yín nìyí, ẹni tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún mi, ati olóòótọ́ ninu nǹkan ti Oluwa. Òun ni yóo ran yín létí àwọn ohun tí mo fi ń ṣe ìwà hù ninu ìgbé-ayé titun ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ gbogbo àwọn ìjọ níbi gbogbo.

18. Àwọn kan ti ń gbéraga bí ẹni pé n kò ní wá sọ́dọ̀ yín.

19. Ṣugbọn mò ń bọ̀ láìpẹ́, bí Oluwa bá fẹ́. N óo wá mọ agbára tí àwọn tí wọn ń gbéraga ní nígbà náà, yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lásán.

20. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu: ti agbára ni!

21. Kí ni ẹ fẹ́? Kí n tọ̀ yín wá pẹlu pàṣán ni, tabi pẹlu ẹ̀mí ìfẹ́ ati ní ìrẹ̀lẹ̀?

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 4