Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 3:18-23 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Bí ẹnìkan ninu yín bá rò pé òun gbọ́n ọgbọ́n ti ayé yìí, kí ó ka ara rẹ̀ sí òmùgọ̀ kí ó lè gbọ́n.

19. Nítorí agọ̀ ni ọgbọ́n ayé yìí lójú Ọlọrun. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn.”

20. Níbòmíràn, ó tún wí pé, “Oluwa mọ̀ pé asán ni èrò-inú àwọn ọlọ́gbọ́n.”

21. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tìtorí eniyan gbéraga, nítorí tiyín ni ohun gbogbo:

22. ati Paulu ni, ati Apolo, ati Peteru, ati ayé yìí, ati ìyè, ati ikú, ati àwọn nǹkan ìsinsìnyìí ati àwọn nǹkan àkókò tí ń bọ̀, tiyín ni ohun gbogbo.

23. Ṣugbọn ti Kristi ni yín, Kristi sì jẹ́ ti Ọlọrun.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 3