Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 3:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará, n kò lè ba yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ti Ẹ̀mí, bíkòṣe bí ẹlẹ́ran-ara, àní gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ ninu Kristi.

2. Wàrà ni mo ti fi ń bọ yín, kì í ṣe oúnjẹ gidi, nítorí nígbà náà ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi. Àní títí di ìsinsìnyìí ẹ kò ì tíì lè jẹ ẹ́,

3. nítorí bí ẹlẹ́ran-ara ni ẹ̀ ń hùwà sibẹ. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí owú jíjẹ ati ìjà bá wà láàrin yín, ṣé kò wá fihàn pé bí ẹlẹ́ran-ara ati eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà.

4. Nítorí nígbà tí ẹnìkan ń sọ pé ẹ̀yìn Paulu ni òun wà, tí ẹlòmíràn ń sọ pé ẹ̀yìn Apolo ni òun wà ní tòun, ó fihàn pé bí eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà.

5. Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an.

6. Èmi gbin irúgbìn, Apolo bomi rin ohun tí mo gbìn, ṣugbọn Ọlọrun ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn dàgbà.

7. Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà.

8. Ọ̀kan ni ẹni tí ó ń gbin irúgbìn ati ẹni tí ó ń bomi rin ín. Nígbà tí ó bá yá, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóo gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.

9. Nítorí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni wá lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ẹ̀yin ni ọgbà Ọlọrun.Tẹmpili Ọlọrun sì ni yín.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 3