Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 16:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun.

16. Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà.

17. Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa.

18. Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.

19. Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa.

20. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín.

21. Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí.

22. Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni! Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀!

23. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.

24. Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 16