Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 14:4-20 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà.

5. Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí.

6. Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ.

7. Bí àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí à ń fi kọ orin, bíi fèrè tabi dùùrù, kò bá dún dáradára, ta ni yóo mọ ohùn orin tí wọn ń kọ?

8. Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun?

9. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni tí ẹ bá ń lo èdè àjèjì, tí ẹ kò lo ọ̀rọ̀ tí ó yé eniyan, báwo ni eniyan yóo ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Afẹ́fẹ́ lásán ni ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ sí.

10. Láìsí àní-àní, oríṣìíríṣìí èdè ni ó wà láyé, ṣugbọn kò sí èyí tí kò ní ìtumọ̀ ninu wọn.

11. Nítorí náà, bí n kò bá gbọ́ èdè kan, mo di aláìgbédè lójú ẹni tí ó bá ń sọ èdè náà, òun náà sì di kògbédè lójú mi.

12. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń tiraka láti ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ máa wá àwọn ẹ̀bùn tí yóo mú ìjọ dàgbà.

13. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ fi níláti gbadura fún ẹ̀bùn láti lè túmọ̀ rẹ̀.

14. Bí mo bá ń fi èdè àjèjì gbadura, ẹ̀mí mi ni ó ń gbadura, ṣugbọn n kò lo òye ti inú ara mi nígbà náà.

15. Kí ni kí á wá wí? N óo gbadura bí Ẹ̀mí bá ti darí mi, ṣugbọn n óo kọrin pẹlu òye.

16. Bí o bá ń gbadura ọpẹ́ ní ọkàn rẹ, bí ẹnìkan bá wà níbẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, báwo ni yóo ṣe lè ṣe “Amin” sí adura ọpẹ́ tí ò ń gbà nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ?

17. Ọpẹ́ tí ò ń ṣe lè dára ṣugbọn kò mú kí ẹlòmíràn lè dàgbà.

18. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí mò ń sọ ọpọlọpọ èdè àjèjì ju gbogbo yín lọ.

19. Ṣugbọn ninu ìjọ, ó yá mi lára kí n sọ ọ̀rọ̀ marun-un pẹlu òye kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jù kí n sọ ọ̀rọ̀ kí ilẹ̀ kún ní èdè àjèjì lọ.

20. Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 14