Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 14:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ máa lépa ìfẹ́. Ṣugbọn ẹ tún máa tiraka láti ní Ẹ̀mí Mímọ́, pàápàá jùlọ, ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀.

2. Nítorí ẹni tí ó bá ń fi èdè sọ̀rọ̀ kò bá eniyan sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Nítorí pé kò sí ẹni tí ó gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Ẹ̀mí ni ó gbé e tí ó fi ń sọ ohun àṣírí tí ó ń sọ tí kò yé eniyan.

3. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń bá eniyan sọ̀rọ̀ fún ìdàgbà ti ẹ̀mí, fún ìtùnú, ati ìwúrí.

4. Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà.

5. Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí.

6. Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ.

7. Bí àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí à ń fi kọ orin, bíi fèrè tabi dùùrù, kò bá dún dáradára, ta ni yóo mọ ohùn orin tí wọn ń kọ?

8. Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun?

9. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni tí ẹ bá ń lo èdè àjèjì, tí ẹ kò lo ọ̀rọ̀ tí ó yé eniyan, báwo ni eniyan yóo ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Afẹ́fẹ́ lásán ni ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ sí.

10. Láìsí àní-àní, oríṣìíríṣìí èdè ni ó wà láyé, ṣugbọn kò sí èyí tí kò ní ìtumọ̀ ninu wọn.

11. Nítorí náà, bí n kò bá gbọ́ èdè kan, mo di aláìgbédè lójú ẹni tí ó bá ń sọ èdè náà, òun náà sì di kògbédè lójú mi.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 14