Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 12:27-31 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ẹ̀yin ni ara Kristi, ẹ̀yà ara rẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín.

28. Oríṣìíríṣìí eniyan ni Ọlọrun yàn ninu ìjọ: àwọn kinni ni àwọn aposteli, àwọn keji, àwọn wolii; àwọn kẹta, àwọn olùkọ́ni; lẹ́yìn náà, àwọn oníṣẹ́ ìyanu, kí ó tó wá kan àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn tabi àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, tabi àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ, ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti sọ èdè àjèjì.

29. Gbogbo yín ni aposteli bí? Àbí gbogbo yín ni wolii? Ṣé gbogbo yín ni olùkọ́ni? Àbí gbogbo yín ni ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìyanu?

30. Kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ ní ẹ̀bùn kí á ṣe ìwòsàn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ lè sọ èdè àjèjì. Àbí gbogbo yín ni ẹ lè túmọ̀ àwọn èdè àjèjì?

31. Ẹ máa fi ìtara lépa àwọn ẹ̀bùn tí ó ga jùlọ.Ṣugbọn n óo fi ọ̀nà kan tí ó dára jùlọ hàn yín.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 12