Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 12:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará, n kò fẹ́ kí nǹkan nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣókùnkùn si yín.

2. Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ jẹ́ aláìmọ Ọlọrun, ẹ̀ ń bọ oriṣa tí kò lè fọhùn. À ń tì yín síwá sẹ́yìn.

3. Nítorí náà, mò ń fi ye yín pé kò sí ẹni tí ó lè máa fi agbára Ẹ̀mí Ọlọrun sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ fi Jesu gégùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè wí pé, “Jesu ni Oluwa,” láìjẹ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí rẹ̀.

4. Oríṣìíríṣìí ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà ni wọ́n ti ń wá.

5. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ iranṣẹ ni ó wà, ṣugbọn Oluwa kan náà ni à ń sìn.

6. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan.

7. Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ń farahàn ninu olukuluku wa fún ire gbogbo wa.

8. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ti fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, a sì fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà.

9. Ẹlòmíràn ní igbagbọ, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà;

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 12