Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 11:10-23 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Nítorí èyí, ó yẹ kí obinrin ní àmì àṣẹ ní orí nítorí àwọn angẹli.

11. Ṣugbọn ṣá, ninu Oluwa, bí obinrin ti nílò ọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin nílò obinrin.

12. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ara ọkunrin ni obinrin ti wá, láti inú obinrin ni ọkunrin náà sì ti wá. Ṣugbọn ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá.

13. Ẹ̀yin náà ẹ ro ọ̀rọ̀ ọ̀hún wò láàrin ara yín. Ǹjẹ́ ó bójú mu pé kí obinrin gbadura sí Ọlọrun láì bo orí?

14. Mo ṣebí ìṣe ẹ̀dá pàápàá kọ yín pé tí ọkunrin bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn, ó fi àbùkù kan ara rẹ̀;

15. bẹ́ẹ̀ sì ni pé ohun ìyìn ni ó jẹ́ fún obinrin tí ó bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn. Nítorí a fi irun gígùn fún obinrin láti bò ó lórí.

16. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun.

17. Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ.

18. Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí.

19. Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn.

20. Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ.

21. Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó!

22. Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí.

23. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi,

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 11