Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 10:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá.

2. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìrìbọmi ninu ìkùukùu ati ninu òkun, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Mose.

3. Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà.

4. Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.

5. Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀.

6. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, pé kí á má ṣe kó nǹkan burúkú lé ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti kó o lé ọkàn.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 10