Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 2:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà, mo pinnu pé n kò tún fẹ́ kí wíwá tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín jẹ́ ti ìbànújẹ́ mọ́.

2. Bí mo bá bà yín ninu jẹ́, ta ni yóo mú inú mi dùn bí kò bá ṣe ẹ̀yin kan náà tí mo bà ninu jẹ́?

3. Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ si yín nìyí, nítorí n kò fẹ́ wá kí n tún ní ìbànújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yin tí ó yẹ kí ẹ fún mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń yọ̀, inú gbogbo yín ni yóo máa dùn.

4. Nítorí pẹlu ọpọlọpọ ìdààmú ati ọkàn wúwo ni mo fi kọ ọ́, kì í ṣe pé kí ó lè bà yín lọ́kàn jẹ́ ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé ìfẹ́ tí mo ní si yín pọ̀ pupọ.

5. Ní ti ẹni tí ó dá ìbànújẹ́ yìí sílẹ̀, èmi kọ́ ni ó bà ninu jẹ́ rárá. Láì tan ọ̀rọ̀ náà lọ títí, bí ó ti wù kí ó mọ, gbogbo yín ni ó bà ninu jẹ́.

6. Ìyà tí ọpọlọpọ ninu yín ti fi jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó.

7. Kí ẹ wá dáríjì í. Kí ẹ fún un ní ìwúrí. Bí ìbànújẹ́ bá tún pọ̀ lápọ̀jù kí ó má baà wó irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.

8. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ jẹ́ kí ó mọ̀ pé ẹ fẹ́ràn òun.

9. Ìdí tí mo fi kọ ìwé sí yín ni láti fi dán yín wò, kí n lè mọ̀ bí ẹ bá ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu ninu ohun gbogbo.

10. Bí ẹ bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi náà dáríjì í. Nítorí tí mo bá ti dáríjì eniyan, (bí nǹkankan bá fi ìgbà kan wà tí mo fi níláti dáríjì ẹnikẹ́ni), mo ṣe é nítorí tiyín níwájú Kristi.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 2