Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 11:1-20 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbà mí láyè kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ bí aṣiwèrè. Ẹ gbà mí láyè.

2. Mò ń jowú nítorí yín, bí Ọlọrun tií jowú. Nítorí èmi ni mo ṣe ètò láti fà yín fún Kristi bí ẹni fa wundia tí ó pé fún ọkọ rẹ̀.

3. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ.

4. Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.

5. N kò rò pé mo kéré sí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní “aposteli” pataki wọnyi!

6. Ọ̀rọ̀ lè má dùn lẹ́nu mi, ṣugbọn mo ní ìmọ̀, ní ọ̀nà gbogbo a ti mú kí èyí hàn si yín ninu ohun gbogbo.

7. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo ṣẹ̀ tí mo fi ara mi sí ipò ìrẹ̀lẹ̀, kí ẹ lè ní ipò gíga? Àbí ẹ̀ṣẹ̀ ni, pé mo waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín láì gba nǹkankan lọ́wọ́ yín?

8. Mo fẹ́rẹ̀ jẹ àwọn ìjọ mìíràn run, tí mò ń gba owó lọ́wọ́ wọn láti ṣe iṣẹ́ fun yín.

9. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo ṣe aláìní, n kò ni ẹnikẹ́ni lára, àwọn arakunrin tí ó wá láti Masedonia ni wọ́n mójútó àwọn ohun tí mo ṣe aláìní. Ninu gbogbo nǹkan, mo ṣe é lófin pé n kò ní wọ̀ yín lọ́rùn, n kò sì ní yí òfin yìí pada!

10. Gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ Kristi ti wà ninu mi, kò sí ohun tí yóo mú mi yipada ninu ohun tí mo fi ń ṣe ìgbéraga ní gbogbo agbègbè Akaya.

11. Nítorí kí ni? A máa ṣe pé n kò fẹ́ràn yín ni? Ọlọrun mọ̀ pé mo fẹ́ràn yín.

12. Bí mo ti ń ṣe ni n óo tún máa ṣe, kí n má baà fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéraga pé iṣẹ́ wọn dàbí tiwa.

13. Aposteli èké ni irú àwọn bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́tàn ni wọ́n, tí wọn ń farahàn bí aposteli Kristi.

14. Irú rẹ̀ kì í ṣe nǹkan ìjọjú, nítorí Satani pàápàá a máa farahàn bí angẹli ìmọ́lẹ̀.

15. Nítorí náà, kò ṣòro fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ láti farahàn bí iranṣẹ tòótọ́. Ṣugbọn ìgbẹ̀yìn wọn yóo rí bí iṣẹ́ wọn.

16. Mo tún wí lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé aṣiwèrè ni mí. Ṣugbọn bí ẹ bá rò bẹ́ẹ̀, ẹ sá gbà mí bí aṣiwèrè, kí n lè fọ́nnu díẹ̀.

17. N kò sọ̀rọ̀ bí onigbagbọ nípa ohun tí mo fi ń fọ́nnu yìí, bí aṣiwèrè ni mò ń sọ̀rọ̀.

18. Ọpọlọpọ ní ń fọ́nnu nípa nǹkan ti ara, ẹ jẹ́ kí èmi náà fọ́nnu díẹ̀!

19. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi ń gba àwọn aṣiwèrè, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n!

20. Bí ẹnìkan bá ń lò yín bí ẹrú, tí ó ń jẹ yín run, tí ó fi okùn mu yín, tí ó ń ṣe fùkẹ̀ láàrin yín, tí ó ń gba yín létí, ẹ ṣetán láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 11