Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 10:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín.

2. Mo bẹ̀ yín, ẹ má ṣe jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹlu ìgbójú, nítorí ó dá mi lójú pé mo lè ko àwọn kan, tí wọ́n sọ pé à ń hùwà bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa lójú.

3. Nítorí à ń gbé ìgbé-ayé wa ninu àìlera ti ara, ṣugbọn a kò jagun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa,

4. nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú,

5. ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu.

6. A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 10