Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kolose 2:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Kristi Jesu bí Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀.

7. Kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ máa dàgbà ninu rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí igbagbọ yín dúró ṣinṣin bí ẹ ti kọ́ láti ṣe, kí ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo.

8. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi.

9. Nítorí pé ninu Kristi tí ó jẹ́ eniyan ni ohun tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ jẹ́, ń gbé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

10. Ó sì ti ṣe yín ní pípé ninu rẹ̀. Òun níí ṣe orí fún gbogbo àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run, ìbáà ṣe ìjọba tabi àwọn aláṣẹ.

11. Ninu Kristi yìí ni a ti kọ yín nílà, kì í ṣe ilà tí a fi ọwọ́ kọ nípa gígé ẹran-ara kúrò, ṣugbọn ilà ti Kristi;

12. nígbà tí a sin yín ninu omi ìrìbọmi, tí ẹ tún jinde nípa igbagbọ pẹlu agbára Ọlọrun tí ó jí Kristi dìde ninu òkú.

13. Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

Ka pipe ipin Kolose 2