Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Juda 1:21-25 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ẹ pa ara yín mọ́ ninu ìfẹ́ Ọlọrun. Ẹ máa retí ìyè ainipẹkun tí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fun yín ninu àánú rẹ̀.

22. Ẹ máa ṣàánú àwọn tí ó ń ṣiyèméjì.

23. Inú iná ni ẹ ti níláti yọ àwọn mìíràn kí ẹ tó lè gbà wọ́n là. Ìbẹ̀rù-bojo ni kí ẹ fi máa ṣàánú àwọn mìíràn. Ẹ níláti kórìíra aṣọ tí ìfẹ́ ara ti da àbààwọ́n sí.

24. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó lè pa yín mọ́ tí ẹ kò fi ní ṣubú, tí ó lè mu yín dúró pẹlu ayọ̀ níwájú ògo rẹ̀ láì lábàwọ́n,

25. Ọlọrun nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa ni ògo, ọlá, agbára ati àṣẹ wà fún, kí á tó dá ayé, ati nisinsinyii ati títí ayé ainipẹkun. Amin.

Ka pipe ipin Juda 1