Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Juda 1:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ṣugbọn ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ̀yin ẹ ranti ohun tí Oluwa wa Jesu Kristi ti ti ẹnu àwọn aposteli rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀.

18. Wọ́n kìlọ̀ fun yín pé ní àkókò ìkẹyìn, àwọn kan yóo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóo máa tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn láì bẹ̀rù Ọlọrun.

19. Àwọn wọnyi ni wọ́n ń ya ara wọn sọ́tọ̀. Wọ́n hùwà bí ẹranko, wọn kò ní Ẹ̀mí Mímọ́.

20. Ṣugbọn ẹ̀yin, àyànfẹ́ mi, ẹ fi igbagbọ yín tí ó mọ́ jùlọ ṣe odi fún ara yín, kí ẹ máa gbadura nípa agbára tí ó wà ninu Ẹ̀mí Mímọ́.

21. Ẹ pa ara yín mọ́ ninu ìfẹ́ Ọlọrun. Ẹ máa retí ìyè ainipẹkun tí Oluwa wa Jesu Kristi yóo fun yín ninu àánú rẹ̀.

22. Ẹ máa ṣàánú àwọn tí ó ń ṣiyèméjì.

23. Inú iná ni ẹ ti níláti yọ àwọn mìíràn kí ẹ tó lè gbà wọ́n là. Ìbẹ̀rù-bojo ni kí ẹ fi máa ṣàánú àwọn mìíràn. Ẹ níláti kórìíra aṣọ tí ìfẹ́ ara ti da àbààwọ́n sí.

24. Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó lè pa yín mọ́ tí ẹ kò fi ní ṣubú, tí ó lè mu yín dúró pẹlu ayọ̀ níwájú ògo rẹ̀ láì lábàwọ́n,

25. Ọlọrun nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa ni ògo, ọlá, agbára ati àṣẹ wà fún, kí á tó dá ayé, ati nisinsinyii ati títí ayé ainipẹkun. Amin.

Ka pipe ipin Juda 1