Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Juda 1:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bàsèjẹ́ ni wọ́n jẹ́ ninu àsè ìfẹ́ ìjọ, wọn kò ní ọ̀wọ̀ nígbà tí ẹ bá jọ ń jẹ, tí ẹ jọ ń mu. Ara wọn nìkan ni wọ́n ń tọ́jú bí olùṣọ́-aguntan tí ń tọ́jú ara rẹ̀ dípò aguntan. Wọ́n dàbí ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń gbá kiri tí kò rọ òjò. Igi tí kò ní èso ní àkókò ìkórè ni wọ́n, wọ́n ti kú sára. Nígbà tí ó bá ṣe, wọn á wó lulẹ̀ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.

13. Ìgbì omi òkun líle ni wọ́n, tí ó ń rú ìwà ìtìjú wọn jáde. Ìràwọ̀ tí kò gbébìkan ni wọ́n. Ààyè wọn ti wà nílẹ̀ fún wọn, ninu òkùnkùn biribiri títí ayé ainipẹkun.

14. Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́,

Ka pipe ipin Juda 1