Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 9:17-30 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Wọ́n tún bi ọkunrin afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ alára sọ nípa lílà tí ó là ọ́ lójú?”Ọkunrin náà ní, “Wolii ni.”

18. Àwọn Juu kò gbàgbọ́ pé ó ti fọ́jú rí kí ó tó ríran títí wọ́n fi pe àwọn òbí ọkunrin náà.

19. Wọ́n bi wọ́n pé, “Ọmọ yín nìyí, tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ti ṣe wá ríran nisinsinyii?”

20. Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé, “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí; ati pé afọ́jú ni a bí i.

21. Ṣugbọn àwa kò mọ̀ bí ó ti ṣe wá ń ríran nisinsinyii. Ẹ bi í, kì í ṣe ọmọde, yóo fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bí ó ti rí.”

22. Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ.

23. Nítorí èyí ni àwọn òbí ọkunrin náà ṣe sọ pé, “Kì í ṣe ọmọde, ẹ bi òun alára léèrè.”

24. Wọ́n tún pe ọkunrin náà tí ó ti fọ́jú rí lẹẹkeji, wọ́n wí fún un pé, “Sọ ti Ọlọrun! Ní tiwa, àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkunrin yìí.”

25. Ọkunrin náà sọ fún wọn pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o, tabi ẹlẹ́ṣẹ̀ kọ́, èmi kò mọ̀. Nǹkankan ni èmi mọ̀: afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, mo ríran.”

26. Wọ́n bi í pé, “Kí ni ó ṣe sí ọ? Báwo ni ó ti ṣe là ọ́ lójú?”

27. Ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ fun yín lẹ́ẹ̀kan ná, ṣugbọn ẹ kò fẹ́ gbọ́. Kí ló dé tí ẹ fi tún fẹ́ gbọ́? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni?”

28. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u, wọ́n ní, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ní tiwa, ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni wá.

29. Àwa mọ̀ pé Ọlọrun ti bá Mose sọ̀rọ̀, ṣugbọn a kò mọ ibi tí eléyìí ti yọ wá.”

30. Ọkunrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ohun ìyanu ni èyí! Ẹ kò mọ ibi tí ó ti yọ wá, sibẹ ó là mí lójú.

Ka pipe ipin Johanu 9