Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 8:27-42 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Wọn kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Baba ni ó ń sọ fún wọn.

28. Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí.

29. Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”

30. Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́.

31. Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́;

32. ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.”

33. Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?”

34. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

35. Ẹrú kì í gbé inú ilé títí, ọmọ níí gbé inú ilé títí.

36. Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ óo di òmìnira nítòótọ́.

37. Mo mọ̀ pé ìran Abrahamu ni yín, sibẹ ẹ̀ ń wá ọ̀nà láti pa mí, nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè ninu yín.

38. Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba mi ni mò ń sọ, ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́ lọ́dọ̀ baba yín ni ẹ̀ ń ṣe.”

39. Wọ́n sọ fún un pé, “Abrahamu ni baba wa.”Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọ Abrahamu ni yín, irú ohun tí Abrahamu ṣe ni ẹ̀ bá máa ṣe.

40. Ṣugbọn ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, bẹ́ẹ̀ sì ni òtítọ́ tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọrun ni mo sọ fun yín. Abrahamu kò hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

41. Irú ohun tí baba yín ṣe ni ẹ̀ ń ṣe.”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í ṣe ọmọ àlè, baba kan ni a ní, òun náà sì ni Ọlọrun.”

42. Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi.

Ka pipe ipin Johanu 8