Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 8:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ó wá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin, ní tiyín, ìsàlẹ̀ ni ẹ ti wá, ṣugbọn ní tèmi, òkè ọ̀run ni mo ti wá. Ti ayé yìí ni yín, èmi kì í ṣe ti ayé yìí.

24. Nítorí náà, mo wí fun yín pé ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nítorí bí ẹ kò bá gbàgbọ́ pé, ‘Èmi ni,’ ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25. Wọ́n bi í pé, “Ta ni ọ́?”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ ẹni tí mo jẹ́ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀.

26. Mo ní ohun pupọ láti sọ nípa yín ati láti fi ṣe ìdájọ́ yín. Olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi níṣẹ́; ohun tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ fún aráyé.”

27. Wọn kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Baba ni ó ń sọ fún wọn.

28. Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí.

29. Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”

30. Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́.

31. Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́;

32. ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.”

33. Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?”

Ka pipe ipin Johanu 8