Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 6:62-71 BIBELI MIMỌ (BM)

62. Tí ẹ bá wá rí Ọmọ-Eniyan tí ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́?

63. Ẹ̀mí ní ń sọ eniyan di alààyè, ẹran-ara kò ṣe anfaani kankan. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ba yín sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ati ti ìyè.

64. Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

65. Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.”

66. Nítorí èyí, ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ̀, wọn kò tún bá a rìn mọ́.

67. Jesu bá bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila pé, “Ẹ̀yin náà fẹ́ lọ bí?”

68. Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni à bá lọ? Ìwọ ni o ní ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun.

69. Ní tiwa, a ti gbàgbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọrun.”

70. Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ̀yin mejila ni mo yàn. Ṣugbọn ẹni ibi ni ọ̀kan ninu yín.”

71. Ó wí èyí nípa Judasi Iskariotu ọmọ Simoni, nítorí òun ni ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ni Judasi Iskariotu yìí.

Ka pipe ipin Johanu 6