Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 21:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, ò ń di ara rẹ ni àmùrè gírí, ò ń lọ sí ibi tí o bá fẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá di arúgbó, ìwọ yóo na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóo wọ aṣọ fún ọ, yóo fà ọ́ lọ sí ibi tí o kò fẹ́ lọ.”

19. (Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”

20. Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”

21. Nígbà tí Peteru rí i, ó bi Jesu pé, “Oluwa, eléyìí ńkọ́?”

22. Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.”

23. Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?”

24. Ọmọ-ẹ̀yìn náà ni ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi. Òun ni ó kọ nǹkan wọnyi: a mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

25. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni Jesu ṣe, bí a bá kọ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé kò ní sí ààyè tó ní gbogbo ayé tí yóo gba ìwé tí a bá kọ wọ́n sí.

Ka pipe ipin Johanu 21