Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 2:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀.

2. Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà.

3. Nígbà tí ọtí tán, ìyá Jesu sọ fún un pé, “Wọn kò ní ọtí mọ́!”

4. Jesu wí fún un pé, “Kí ni tèmi ati tìrẹ ti jẹ́, obinrin yìí? Àkókò mi kò ì tíì tó.”

5. Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ ṣe ohunkohun tí ó bá wí fun yín.”

6. Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa.

7. Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn.

8. Ó bá tún wí fún wọn pé, “Ẹ bù ninu rẹ̀ lọ fún alága àsè.” Wọ́n bá bù ú lọ.

Ka pipe ipin Johanu 2