Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 18:26-40 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ọ̀kan ninu àwọn ẹrú Olórí Alufaa, tí ó jẹ́ ẹbí ẹni tí Peteru gé létí bi Peteru pé, “Ǹjẹ́ n kò rí ọ ninu ọgbà pẹlu rẹ̀?”

27. Peteru tún sẹ́. Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kan bá kọ.

28. Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.

29. Pilatu bá jáde lọ sọ́dọ̀ wọn lóde, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀sùn wo ni ẹ fi kan ọkunrin yìí?”

30. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí ọkunrin yìí kò bá ṣe nǹkan burúkú ni, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́.”

31. Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un lọ, kí ẹ ṣe ìdájọ́ fún un bí òfin yín.”Ṣugbọn àwọn Juu sọ fún un pé, “A kò ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́ ikú fún ẹnikẹ́ni.”

32. Gbolohun yìí jáde kí ọ̀rọ̀ Jesu lè ṣẹ nígbà tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóo kú.

33. Pilatu bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”

34. Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?”

35. Pilatu dáhùn pé, “Èmi í ṣe Juu bí? Àwọn eniyan rẹ ati àwọn olórí alufaa ni wọ́n fà ọ́ wá sọ́dọ̀ mi. Kí ni o ṣe?”

36. Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.”

37. Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”

38. Pilatu bi í pé, “Kí ni òtítọ́?”Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tún jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn Juu, ó sọ fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.

39. Ṣugbọn ẹ ní àṣà kan, pé kí n dá ẹnìkan sílẹ̀ fun yín ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá. Ṣé ẹ fẹ́ kí n dá ‘Ọba àwọn Juu’ sílẹ̀ fun yín?”

40. Wọ́n tún kígbe pé, “Òun kọ́! Baraba ni kí o dá sílẹ̀!” (Ọlọ́ṣà paraku ni Baraba yìí.)

Ka pipe ipin Johanu 18