Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 18:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

2. Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

3. Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà.

4. Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”

5. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.”Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.

6. Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.

7. Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”

8. Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.”

Ka pipe ipin Johanu 18