Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 16:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Mo sọ gbogbo nǹkan yìí fun yín kí igbagbọ yín má baà yẹ̀.

2. Wọn yóo le yín jáde kúrò ninu ilé ìpàdé wọn. Èyí nìkan kọ́, àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé ẹni tí ó bá ṣe ikú pa yín yóo rò pé òun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọrun ni.

3. Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.

4. Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín.“N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín.

5. Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’

6. Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín.

7. Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín.

8. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun.

Ka pipe ipin Johanu 16