Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 15:3-23 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín.

4. Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi.

5. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi.

6. Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná.

7. Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà.

8. Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

9. Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi.

10. Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀.

11. “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

12. Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.

13. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

14. Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín.

15. N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín.

16. Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi.

17. Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín.

18. “Bí aráyé bá kórìíra yín, kí ẹ mọ̀ pé èmi ni wọ́n kọ́ kórìíra ṣáájú yín.

19. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín.

20. Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́.

21. Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

22. Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

23. Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi.

Ka pipe ipin Johanu 15