Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 15:19-27 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín.

20. Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́.

21. Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

22. Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

23. Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi.

24. Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi.

25. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’

26. “Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi.

27. Ẹ̀yin náà yóo sì jẹ́rìí mi nítorí ẹ ti wà pẹlu mi láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi.

Ka pipe ipin Johanu 15