Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 15:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Èmi ni àjàrà tòótọ́. Baba mi ni àgbẹ̀ tí ń mójútó ọgbà àjàrà.

2. Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ.

3. Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín.

4. Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi.

Ka pipe ipin Johanu 15