Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 14:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé.

24. Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

25. “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín.

26. Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín.

27. “Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín.

28. Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ.

29. Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán.

30. N kò tún ní ohun pupọ ba yín sọ mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ̀. Kò ní agbára kan lórí mi.

31. Ṣugbọn kí ayé lè mọ̀ pé mo fẹ́ràn Baba ni mo ṣe ń ṣe bí Baba ti pàṣẹ fún mi.“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á kúrò níhìn-ín.

Ka pipe ipin Johanu 14