Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 14:13-23 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ.

14. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é.

15. “Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́.

16. N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae.

17. Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.

18. “Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín.

19. Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè.

20. Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín.

21. “Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.”

22. Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?”

23. Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé.

Ka pipe ipin Johanu 14