Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 13:29-38 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”

30. Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà.

31. Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan.

32. Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ.

33. Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.

34. Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.

35. Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”

36. Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?”Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.”

37. Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.”

38. Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta.

Ka pipe ipin Johanu 13