Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 13:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín?

13. Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.

14. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín.

15. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe.

16. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ.

17. Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.

18. “Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’

19. Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán.

20. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”

21. Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”

22. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú.

23. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí.

24. Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.

25. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”

26. Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu.

Ka pipe ipin Johanu 13