Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 12:3-22 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé.

4. Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé,

5. “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?”

6. Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́.

7. Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.

8. Nígbà gbogbo ni àwọn talaka wà lọ́dọ̀ yín, ṣugbọn èmi kò ní sí lọ́dọ̀ yín nígbà gbogbo.”

9. Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú.

10. Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru,

11. nítorí pé nítorí rẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn Juu ṣe ń kúrò ninu ẹ̀sìn wọn, tí wọn ń gba Jesu gbọ́.

12. Ní ọjọ́ keji, ọpọlọpọ eniyan tí ó wá ṣe àjọ̀dún gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.

13. Wọ́n bá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa ati ọba Israẹli.”

14. Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,

15. “Má bẹ̀rù mọ́, ọdọmọbinrin Sioni,Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

16. Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i.

17. Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí.

18. Nítorí èyí ni àwọn eniyan ṣe lọ pàdé rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí.

19. Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!”

20. Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà.

21. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”

22. Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu.

Ka pipe ipin Johanu 12