Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 12:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde.

2. Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun.

3. Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé.

4. Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé,

5. “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?”

6. Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́.

7. Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.

8. Nígbà gbogbo ni àwọn talaka wà lọ́dọ̀ yín, ṣugbọn èmi kò ní sí lọ́dọ̀ yín nígbà gbogbo.”

9. Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú.

10. Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru,

11. nítorí pé nítorí rẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn Juu ṣe ń kúrò ninu ẹ̀sìn wọn, tí wọn ń gba Jesu gbọ́.

Ka pipe ipin Johanu 12