Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 10:32-42 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”

33. Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.”

34. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’

35. Ìwé Mímọ́ kò ṣe é parẹ́. Bí Ọlọrun bá pe àwọn tí ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ní ọlọ́run,

36. kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé?

37. Bí n kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.

38. Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.”

39. Nígbà náà ni wọ́n tún ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ó jáde kúrò ní àrọ́wọ́tó wọn.

40. Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀.

41. Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.”

42. Ọpọlọpọ eniyan bá gbà á gbọ́ níbẹ̀.

Ka pipe ipin Johanu 10