Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 1:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.

19. Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”

20. Ó sọ òtítọ́, kò parọ́, ó ní, “Èmi kì í ṣe Mesaya náà.”

21. Wọ́n wá bi í pé, “Ta wá ni ọ́? Ṣé Elija ni ọ́ ni?”Ó ní, “Èmi kì í ṣe Elija.”Wọ́n tún bi í pé, “Ìwọ ni wolii tí à ń retí bí?”Ó ní, “Èmi kọ́.”

22. Wọ́n bá tún bèèrè pé, “Ó dára, ta ni ọ́? Ó yẹ kí á lè rí èsì mú pada fún àwọn tí wọ́n rán wa wá. Kí ni o sọ nípa ara rẹ?”

23. Ó bá dáhùn gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti sọ pé:“Èmi ni ‘ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé:Ẹ ṣe ọ̀nà tí ó tọ́ fún Oluwa.’ ”

24. Àwọn Farisi ni ó rán àwọn eniyan sí i.

25. Wọ́n wá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi nígbà tí kì í ṣe ìwọ ni Mesaya tabi Elija tabi wolii tí à ń retí?”

26. Johanu dá wọn lóhùn pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ẹnìkan wà láàrin yín tí ẹ kò mọ̀,

27. ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣugbọn n kò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”

28. Ní Bẹtani tí ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi.

29. Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ.

Ka pipe ipin Johanu 1