Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu Kinni 5:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ẹ̀rí náà ni pé Ọlọrun ti fún wa ní ìyè ainipẹkun, ìyè yìí sì wà ninu Ọmọ rẹ̀.

12. Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè.

13. Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun.

14. Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa.

15. Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà.

16. Bí ẹnikẹ́ni bá rí arakunrin rẹ̀ tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ kan, tí kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ mọ́ ti ikú, kí ó gbadura fún un, Ọlọrun yóo fún un ní ìyè. Mò ń sọ nípa àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò jẹ mọ́ ti ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ. N kò wí pé kí eniyan gbadura fún irú rẹ̀.

17. Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí kò jẹ mọ́ ti ikú.

18. A mọ̀ pé kò sí ọmọ Ọlọrun kan tíí máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ń pa á mọ́, Èṣù kò sì ní fọwọ́ kàn án.

19. A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.

20. A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.

21. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má bá wọn bọ oriṣa.

Ka pipe ipin Johanu Kinni 5