Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu Kẹta 1:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ó yẹ kí á máa ran irú wọn lọ́wọ́ kí á lè jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu wọn ninu iṣẹ́ òtítọ́.

9. Mo kọ ìwé kan sí ìjọ ṣugbọn Diotirefe tí ó fẹ́ ipò aṣiwaju láàrin ìjọ kò gba ohun tí mo sọ.

10. Nítorí náà, nígbà tí mo bá dé, n óo ranti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń ṣe, tí ó ń sọ ìsọkúsọ nípa mi. Kò fi ọ̀ràn mọ bẹ́ẹ̀; kò gba àwọn arakunrin tí wọ́n wá, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ gbà wọ́n, kò jẹ́ kí wọ́n gbà wọ́n, ó tún fẹ́ yọ wọ́n kúrò ninu ìjọ!

11. Olùfẹ́, má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú, ṣugbọn tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti wá. Ẹni tí ó bá ń ṣe burúkú kò mọ Ọlọrun.

12. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń ròyìn Demeteriu ní rere. Òtítọ́ pàápàá ń jẹ́rìí rẹ̀. Èmi náà jẹ́rìí sí i, o sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí mi.

13. Mo ní ohun pupọ tí mo fẹ́ bá ọ sọ, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé.

14. Mo ní ìrètí ati rí ọ láìpẹ́, nígbà náà a óo lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju.

15. Kí alaafia máa bá ọ gbé. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa níhìn-ín kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ka pipe ipin Johanu Kẹta 1