Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu Kẹta 1:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí.

3. Inú mi dùn nígbà tí àwọn arakunrin dé, tí wọ́n ròyìn rẹ pé o ṣe olóòótọ́ sí ọ̀nà òtítọ́, ati pé ò ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.

4. Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.

5. Olùfẹ́, ohun rere ni ò ń ṣe fún àwọn arakunrin, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àlejò.

6. Níwájú gbogbo ìjọ níhìn-ín wọ́n jẹ́rìí sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ fún òṣìṣẹ́ Ọlọrun.

Ka pipe ipin Johanu Kẹta 1